Isaiah 40:6-9


6 aOhùn kan wí pé, “Kígbe sókè.”
Èmi sì sọ pé, “Igbe kí ni èmi ó ké?”

“Gbogbo ènìyàn dàbí i koríko,
àti gbogbo ògo wọn dàbí ìtànná igbó.
7Koríko ń rọ ìtànná sì ń rẹ̀,
nítorí èémí Olúwa ń fẹ́ lù wọ́n.
Nítòótọ́ koríko ni àwọn ènìyàn.
8Koríko ń rọ ìtànná sì ń rẹ̀,
ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa dúró títí láé.”

9 bÌwọ tí o mú ìyìn ayọ̀ wá sí Sioni,
lọ sí orí òkè gíga.
Ìwọ tí ó mú ìyìn ayọ̀ wá sí Jerusalẹmu,
gbé ohùn rẹ sókè pẹ̀lú ariwo,
gbé e sókè, má ṣe bẹ̀rù;
sọ fún àwọn ìlú u Juda,
“Ọlọ́run rẹ nìyìí!”
Copyright information for YorBMYO